Mat 25:1-30

Mat 25:1-30 YBCV

NIGBANA li a o fi ijọba ọrun wé awọn wundia mẹwa, ti o mu fitila wọn, ti nwọn si jade lọ ipade ọkọ iyawo. Marun ninu wọn ṣe ọlọgbọn, marun si ṣe alaigbọn. Awọn ti o ṣe alaigbọ́n mu fitila wọn, nwọn kò si mu oróro lọwọ: Ṣugbọn awọn ọlọgbọn mu oróro ninu kolobo pẹlu fitila wọn. Nigbati ọkọ iyawo pẹ, gbogbo wọn tõgbé, nwọn si sùn. Ṣugbọn lãrin ọganjọ, igbe ta soke, wipe, Wo o, ọkọ, iyawo mbọ̀; ẹ jade lọ ipade rẹ̀. Nigbana ni gbogbo awọn wundia wọnni dide, nwọn, si tún fitila wọn ṣe. Awọn alaigbọn si wi fun awọn ọlọgbọn pe, Fun wa ninu oróro nyin; nitori fitila wa nkú lọ. Ṣugbọn awọn ọlọ́gbọn da wọn li ohùn, wipe, Bẹ̃kọ; ki o má ba ṣe alaito fun awa ati ẹnyin: ẹ kuku tọ̀ awọn ti ntà lọ, ki ẹ si rà fun ara nyin. Nigbati nwọn si nlọ rà, ọkọ iyawo de; awọn ti o si mura tan bá a wọle lọ si ibi iyawo: a si tì ilẹkun. Ni ikẹhin li awọn wundia iyokù si de, nwọn nwipe, Oluwa, Oluwa, ṣilẹkun fun wa. Ṣugbọn o dahùn, wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kò mọ̀ nyin. Nitorina, ẹ mã ṣọna, bi ẹnyin ko ti mọ̀ ọjọ, tabi wakati tí Ọmọ-enia yio de. Nitori ijọba ọrun dabi ọkunrin kan ti o nlọ si àjo, ẹniti o pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si kó ẹrù rẹ̀ fun wọn. O si fi talenti marun fun ọkan, o fi meji fun ẹnikeji, ati ọkan fun ẹnikẹta; o fifun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti ri; lẹsẹkanna o mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n. Nigbana li eyi ti o gbà talenti marun lọ, ọ fi tirẹ̀ ṣòwo, o si jère talenti marun miran. Gẹgẹ bẹ̃li eyi ti o gbà meji, on pẹlu si jère meji miran. Ṣugbọn eyi ti o gbà talenti kan lọ, o wà ilẹ, o si rì owo oluwa rẹ̀. Lẹhin igba ti o pẹ titi, oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni de, o ba wọn ṣiro. Eyi ti o gbà talenti marun si wá, o si mu talenti marun miran wá pẹlu, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti marun fun mi: si wò o, mo jère talenti marun miran. Oluwa rẹ̀ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwo bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ. Eyi ti o gbà talenti meji pẹlu si wá, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti meji fun mi: wo o, mo jère talenti meji miran. Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ. Eyi ti o gbà talenti kan si wá, o ni, Oluwa, mo mọ̀ ọ pe onroro enia ni iwọ iṣe, iwọ nkore nibiti iwọ kò gbe funrugbin si, iwọ si nṣà nibiti iwọ kò fẹ́ka si: Emi si bẹ̀ru, mo si lọ pa talenti rẹ mọ́ ninu ilẹ: wo o, nkan rẹ niyi. Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si: Nitorina iwọ iba fi owo mi si ọwọ́ awọn ti npowodà, nigbati emi ba de, emi iba si gbà nkan mi pẹlu elé. Nitorina ẹ gbà talenti na li ọwọ́ rẹ̀, ẹ si fifun ẹniti o ni talenti mẹwa. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ́ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni. Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.

Video for Mat 25:1-30