Jesu si dahùn, o si tún fi owe sọ̀rọ fun wọn pe,
Ijọba ọrun dabi ọba kan, ti o ṣe igbeyawo fun ọmọ rẹ̀.
O si rán awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọ ipè awọn ti a ti pè tẹlẹ si ibi iyawo: ṣugbọn nwọn kò fẹ wá.
O si tún rán awọn ọmọ-ọdọ miran, wipe, Ẹ wi fun awọn ti a pè pe, Wò o, mo se onjẹ mi tan: a pa malu ati gbogbo ẹran abọpa mi, a si ṣe ohun gbogbo tan: ẹ wá si ibi iyawo.
Ṣugbọn nwọn ko fi pè nkan, nwọn ba tiwọn lọ, ọkan si ọ̀na oko rẹ̀, omiran si ọ̀na òwò rẹ̀:
Awọn iyokù si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, nwọn ṣe àbuku si wọn, nwọn si lù wọn pa.
Nigbati ọba si gbọ́ eyi, o binu: o si rán awọn ogun rẹ̀ lọ, o pa awọn apania wọnni run, o si kun ilu wọn.
Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A se ase iyawo tan, ṣugbọn awọn ti a ti pè kò yẹ.
Nitorina ẹ lọ si ọ̀na opópo, iyekiye ẹniti ẹ ba ri, ẹ pè wọn wá si ibi iyawo.
Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ wọnni si jade lọ si ọ̀na opópo, nwọn si kó gbogbo awọn ẹniti nwọn ri jọ, ati buburu ati rere: ibi ase iyawo si kún fun awọn ti o wá jẹun.
Nigbati ọba na wá iwò awọn ti o wá jẹun, o ri ọkunrin kan nibẹ̀ ti kò wọ̀ aṣọ iyawo:
O si bi i pe, Ọrẹ́, iwọ ti ṣe wọ̀ ìhin wá laini aṣọ iyawo? Kò si le fọhùn.
Nigbana li ọba wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ di i tọwọ tẹsẹ, ẹ gbé e kuro, ki ẹ si sọ ọ sinu òkunkun lode; nibẹ̀ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.
Nitori ọ̀pọlọpọ li a pè, ṣugbọn diẹ li a yàn.