Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle. O si wi fun wọn pe, A ti kọ ọ pe, Ile adura li a ó ma pè ile mi; ṣugbọn ẹnyin sọ ọ di ihò ọlọṣà. Ati awọn afọju ati awọn amukun wá sọdọ rẹ̀ ni tẹmpili; o si mu wọn larada. Ṣugbọn nigbati awọn olori alufa ati awọn akọwe ri ohun iyanu ti o ṣe, ati bi awọn ọmọ kekeke ti nke ni tẹmpili, wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi; inu bi wọn gidigidi, Nwọn si wi fun u pe, Iwọ gbọ́ eyiti awọn wọnyi nwi? Jesu si wi fun wọn pe, Bẹ̃ni; ẹnyin kò ti kà a ninu iwe pe, Lati ẹnu awọn ọmọ-ọwọ́ ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyìn pé? O si fi wọn silẹ, o jade kuro ni ilu na lọ si Betani; o wọ̀ sibẹ̀.
Kà Mat 21
Feti si Mat 21
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 21:12-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò