Nigbana ni Herodu pè awọn amoye na si ìkọkọ, o sì bi wọn lẹsọlẹsọ akokò ti irawọ na hàn. O si rán wọn lọ si Betlehemu, o wipe, Ẹ lọ íwadi ti ọmọ-ọwọ na lẹsọlẹsọ; nigbati ẹnyin ba si ri i, ẹ pada wá isọ fun mi, ki emi ki o le wá iforibalẹ fun u pẹlu. Nigbati nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ọba, nwọn lọ; si wò o, irawọ ti nwọn ti ri lati ìha ìla-õrùn wá, o ṣãju wọn, titi o fi wá iduro loke ibiti ọmọ-ọwọ na gbé wà. Nigbati nwọn si ri irawọ na, nwọn yọ̀ ayọ nlanla. Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia. Bi Ọlọrun ti kìlọ fun wọn li oju alá pe, ki nwọn ki o máṣe pada tọ̀ Herodu lọ mọ́, nwọn gbà ọ̀na miran lọ si ilu wọn.
Kà Mat 2
Feti si Mat 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 2:7-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò