Nigbati nwọn si ti lọ, kiyesi i, angẹli Oluwa yọ si Josefu li oju alá, o wipe, Dide gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ̀, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ̀ titi emi o fi sọ fun ọ; nitori Herodu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a.
Nigbati o si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀ li oru, o si lọ si Egipti;
O si wà nibẹ̀ titi o fi di igba ikú Herodu; ki eyi ti Oluwa wi lati ẹnu woli nì ki o le ṣẹ, pe, Ni Egipti ni mo ti pè ọmọ mi jade wá.
Nigbati Herodu ri pe, on di ẹni itanjẹ lọdọ awọn amoye, o binu gidigidi, o si ranṣẹ, o si pa gbogbo awọn ọmọ ti o wà ni Betlehemu ati ni ẹkùn rẹ̀, lati awọn ọmọ ọdún meji jalẹ gẹgẹ bi akokò ti o ti bere lẹsọlẹsọ lọwọ awọn amoye na.
Nigbana li eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Jeremiah wa ṣẹ, pe,
Ni Rama ni a gbọ́ ohùn, ohùnréré, ati ẹkún, ati ọ̀fọ nla, Rakeli nsọkun awọn ọmọ rẹ̀ ko gbipẹ, nitoriti nwọn ko si.
Nigbati Herodu si kú, kiyesi i, angẹli Oluwa kan yọ si Josefu li oju alá ni Egipti,
Wipe, Dide, mu ọmọ-ọwọ na, ati iya rẹ̀, ki o si lọ si ilẹ Israeli: nitori awọn ti nwá ẹmí ọmọ-ọwọ na lati pa ti kú.
O si dide, o mu ọmọ-ọwọ na ati iya rẹ̀, o si wá si ilẹ Israeli.
Ṣugbọn nigbati o gbọ́ pe Arkelau jọba ni Judea ni ipò Herodu baba rẹ̀, o bẹ̀ru lati lọ sibẹ̀; bi Ọlọrun si ti kìlọ fun u li oju alá, o yipada si apa Galili.
Nigbati o si wá, o joko ni ilu kan ti a npè ni Nasareti; ki eyi ti a ti sọ li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, A o pè e ni ará Nasareti.