Mat 19

19
Ẹ̀kọ́ nípa Ipò Ọkọ ati Aya sí Ara Wọn
(Mak 10:1-12)
1O si ṣe, nigbati Jesu pari ọ̀rọ wọnyi tan, o kuro ni Galili, o si lọ si ẹkùn Judea li oke odò Jordani.
2Ọpọ ijọ enia si tọ̀ ọ lẹhin, o si mu wọn larada nibẹ̀.
3Awọn Farisi si wá sọdọ rẹ̀, nwọn ndán a wò, nwọn si wi fun u pe, O ha tọ́ fun ọkunrin ki o kọ̀ aya rẹ̀ silẹ nitori ọ̀ran gbogbo?
4O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a pe, ẹniti o dá wọn nigba àtetekọṣe o da wọn ti akọ ti abo,
5 O si wipe, Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, yio famọ́ aya rẹ̀; awọn mejeji a si di ara kan.
6 Nitorina nwọn ki iṣe meji mọ́ bikoṣe ara kan. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn.
7Nwọn wi fun u pe, Ẽṣe ti Mose fi aṣẹ fun wa, wipe, ki a fi iwe ikọsilẹ fun u, ki a si kọ̀ ọ silẹ?
8O wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin ni Mose ṣe jẹ fun nyin lati mã kọ̀ aya nyin silẹ, ṣugbọn lati igba àtetekọṣe wá kò ri bẹ̃.
9 Mo si wi fun nyin, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣepe nitori àgbere, ti o si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga: ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga.
10Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Bi ọ̀ran ọkunrin ba ri bayi si aya rẹ̀, kò ṣànfani lati gbé iyawo.
11Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Gbogbo enia kò le gbà ọ̀rọ yi, bikoṣe awọn ẹniti a fi bùn.
12 Awọn iwẹfa miran mbẹ, ti a bí bẹ̃ lati inu iya wọn wá: awọn iwẹfa miran mbẹ ti awọn araiye sọ di iwẹfa: awọn iwẹfa si wà, awọn ti o sọ ara wọn di iwẹfa nitori ijọba ọrun. Ẹniti o ba le gbà a, ki o gbà a.
Jesu Súre fún Àwọn Ọmọde
(Mak 10:13-16; Luk 18:15-17)
13Nigbana li a gbé awọn ọmọ-ọwọ wá sọdọ rẹ̀ ki o le fi ọwọ́ le wọn, ki o si gbadura: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba wọn wi.
14Ṣugbọn Jesu ni, Jọwọ awọn ọmọ kekere, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun ati wá sọdọ mi; nitori ti irú wọn ni ijọba ọrun.
15O si fi ọwọ́ le wọn, o si lọ kuro nibẹ̀.
Ìtàn Ọdọmọkunrin Ọlọ́rọ̀
(Mak 10:17-31; Luk 18:18-30)
16Si kiyesi i, ẹnikan tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Olukọni rere, ohun rere kili emi o ṣe, ki emi ki o le ni ìye ainipẹkun?
17O si wi fun u pe, Eṣe ti iwọ fi pè mi li ẹni rere? ẹni rere kan kò si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun: ṣugbọn bi iwọ ba nfẹ wọ̀ ibi ìye, pa ofin mọ́.
18O bi i lẽre pe, Ewo? Jesu wipe, Iwọ kò gbọdọ pa enia; Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga; Iwọ kò gbọdọ jale; Iwọ kò gbọdọ jẹri eke;
19 Bọwọ fun baba on iya rẹ; ati ki iwọ fẹ aladugbo rẹ bi ara rẹ.
20Ọmọdekunrin na wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi ni mo ti pamọ́ lati igba ewe mi wá: kili o kù mi kù?
21Jesu wi fun u pe, Bi iwọ ba nfẹ pé, lọ tà ohun ti o ni, ki o si fi tọrẹ fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá ki o mã tọ̀ mi lẹhin.
22Ṣugbọn nigbati ọmọdekunrin na gbọ́ ọ̀rọ na, o jade lọ pẹlu ibanujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pupọ̀.
23Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, o ṣoro gidigidi fun ọlọrọ̀ lati wọ ijọba ọrun.
24 Mo si wi fun nyin ẹ̀wẹ, O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.
25Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ ọ, ẹnu yà wọn gidigidi, nwọn wipe, Njẹ tali o ha le là?
26Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe.
27Nigbana ni Peteru dahùn, o si wi fun u pe, Wò o, awa ti fi gbogbo rẹ̀ silẹ, awa si ntọ̀ ọ lẹhin; njẹ kili awa o ha ni?
28Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, pe ẹnyin ti ẹ ntọ̀ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigbati Ọmọ-enia yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀, ẹnyin o si joko pẹlu lori itẹ́ mejila, ẹnyin o ma ṣe idajọ awọn ẹ̀ya Israeli mejila.
29 Ati gbogbo ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori orukọ mi, nwọn o ri ọ̀rọrun gbà, nwọn o si jogún ìye ainipẹkun.
30 Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mat 19: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀