Mat 18:1-5

Mat 18:1-5 YBCV

LAKOKÒ na li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Tali ẹniti o pọ̀ju ni ijọba ọrun? Jesu si pe ọmọ kekere kan sọdọ rẹ̀, o mu u duro larin wọn, O si wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun. Nitorina ẹnikẹni ti o ba rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ bi ọmọ kekere yi, on na ni yio pọ̀ju ni ijọba ọrun. Ẹniti o ba si gbà irú ọmọ kekere yi kan, li orukọ mi, o gbà mi

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ