Jesu si dahùn, o wipe, A! iran alaigbàgbọ́ ati arekereke yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? Gbé ọmọ na tọ̀ mi wá nihin. Jesu si ba a wi, ẹmi èṣu na si jade kuro lara rẹ̀; a si mu ọmọ na larada ni wakati kanna. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá lẹhin, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti awa kò fi le lé e jade? Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́ nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe.
Kà Mat 17
Feti si Mat 17
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 17:17-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò