LẸHIN ijọ mẹfa Jesu mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin rẹ̀, o si mu wọn wá sori òke giga li apakan,
Ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn; oju rẹ̀ si nràn bi õrùn; aṣọ rẹ̀ si fún, o dabi imọle.
Si wo o, Mose ati Elijah yọ si wọn, nwọn mba a sọ̀rọ.
Peteru si dahùn, o si wi fun Jesu pe, Oluwa, o dara fun wa lati mã gbé ihin: bi iwọ ba fẹ, awa o pa agọ́ mẹta sihin; ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah.
Bi o ti nwi lọwọ, wo o, awọsanma didán ṣiji bò wọn: si wo o, ohùn kan lati inu awọsanma wá, ti o wipe, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dun si gidigidi; ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.
Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́, nwọn da oju wọn bolẹ, ẹru si bà wọn gidigidi.
Jesu si wá, o fi ọwọ́ bà wọn, o si wipe, Ẹ dide, ẹ má bẹ̀ru.
Nigbati nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn kò ri ẹnikan, bikoṣe Jesu nikan.
Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, Jesu kìlọ fun wọn pe, Ẹ máṣe sọ̀rọ iran na fun ẹnikan, titi Ọmọ-enia yio fi tun jinde kuro ninu okú.