Mat 13:1-23

Mat 13:1-23 YBCV

LI ọjọ kanna ni Jesu ti ile jade, o si joko leti okun. Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun. O si fi owe ba wọn sọ̀rọ ohun pipọ, o wipe, Wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin; Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ; Nigbati õrùn si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn kò ni gbongbo, nwọn si gbẹ. Diẹ si bọ́ sãrin ẹ̀gún; nigbati ẹ̀gún si dàgba soke, o fun wọn pa. Ṣugbọn omiran bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ wá, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti iwọ fi nfi owe ba wọn sọ̀rọ? O si dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba ọrun, ṣugbọn awọn li a kò fifun. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a ó fifun, on o si ni li ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti ko ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni. Nitorina ni mo ṣe nfi owe ba wọn sọ̀rọ; nitori ni riri, nwọn kò ri, ati ni gbigbọ, nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni kò yé wọn. Si ara wọn ni ọrọ̀ Isaiah wolí si ti ṣẹ, ti o wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati riri ẹnyin o ri, ẹnyin kì yio si moye. Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo ọ̀ran igbọ́, oju wọn ni nwọn si dì; nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi àiya wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki emi ki o má ba mu wọn larada. Ṣugbọn ibukun ni fun oju nyin, nitoriti nwọn ri, ati fun etí nyin, nitoriti nwọn gbọ́. Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ wolĩ ati olododo ni nfẹ ri ohun ti ẹnyin ri, nwọn kò si ri wọn; nwọn si nfẹ gbọ́ ohun ti ẹ gbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn. Nitorina ẹ gbọ́ owe afunrugbin. Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na. Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan. Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀. Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso. Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa