O si ṣe, nigbati Jesu pari aṣẹ rẹ̀ tan fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila, o ti ibẹ̀ rekọja lati ma kọni, ati lati ma wasu ni ilu wọn gbogbo. Nigbati Johanu gburo iṣẹ Kristi ninu tubu, o rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji, O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran? Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ si sọ ohun wọnyi ti ẹnyin gbọ́, ti ẹ si ri fun Johanu: Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi. Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti kì yio ri ohun ikọsẹ ninu mi.
Kà Mat 11
Feti si Mat 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 11:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò