Mal 3:10-12

Verse Images for Mal 3:10-12

Mal 3:10-12 - Ẹ mu gbogbo idamẹwa wá si ile iṣura, ki onjẹ ba le wà ni ile mi, ẹ si fi eyi dán mi wò nisisiyi, bi emi ki yio ba ṣi awọn ferese ọrun fun nyin, ki nsi tú ibukún jade fun nyin, tobẹ̃ ti ki yio si aye to lati gbà a.
Emi o si ba ajẹnirun wi nitori nyin, on kì o si run eso ilẹ nyin, bẹ̃ni àjara nyin kì o rẹ̀ dànu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Gbogbo orilẹ-ède ni yio si pè nyin li alabukún fun: nitori ẹnyin o jẹ ilẹ ti o wuni, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa