O si wi fun ẹlomiran pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn o wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinku baba mi na. Jesu si wi fun u pe, Jẹ́ ki awọn okú ki o mã sinkú ara wọn: ṣugbọn iwọ lọ ki o si mã wãsu ijọba Ọlọrun. Ẹlomiran si wi fun u pe, Oluwa, emi nfẹ lati mã tọ̀ ọ lẹhin; ṣugbọn jẹ ki emi ki o pada lọ idagbere fun awọn ara ile mi. Jesu si wi fun u pe, Kò si ẹni, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ le ohun-elo itulẹ, ti o si wò ẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun.
Kà Luk 9
Feti si Luk 9
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 9:59-62
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò