Luk 9:28-48

Luk 9:28-48 YBCV

O si ṣe bi iwọn ijọ kẹjọ lẹhin ọ̀rọ wọnyi, o mu Peteru, ati Johanu, ati Jakọbu, o gùn ori òke lọ lati gbadura. Bi o si ti ngbadura, àwọ oju rẹ̀ yipada, aṣọ rẹ̀ si fun lawu, o njo fòfo. Si kiyesi i, awọn ọkunrin meji, ti iṣe Mose on Elijah, nwọn mba a sọ̀rọ: Ti nwọn fi ara hàn ninu ogo, nwọn si nsọ̀rọ ikú rẹ̀, ti on ó ṣe pari ni Jerusalemu. Ṣugbọn oju Peteru ati ti awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ wuwo fun õrun. Nigbati nwọn si tají, nwọn ri ogo rẹ̀, ati ti awọn ọkunrin mejeji ti o ba a duro. O si ṣe, nigbati nwọn lọ kuro lọdọ rẹ̀, Peteru wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa ki a mã gbé ihinyi: jẹ ki awa ki o pa agọ́ mẹta; ọkan fun iwọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah: kò mọ̀ eyi ti o nwi. Bi o ti nsọ bayi, ikũkũ kan wá, o ṣiji bò wọn: ẹ̀ru si ba wọn nigbati nwọn nwọ̀ inu ikuku lọ. Ohùn kan si ti inu ikũkũ wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. Nigbati ohùn na si dakẹ, Jesu nikanṣoṣo li a ri. Nwọn si pa a mọ́, nwọn kò si sọ ohunkohun ti nwọn ri fun ẹnikẹni ni ijọ wọnni. O si ṣe, ni ijọ keji, nigbati nwọn sọkalẹ lati ori òke wá, ọ̀pọ awọn enia wá ipade rẹ̀. Si kiyesi i, ọkunrin kan ninu ijọ kigbe soke, wipe, Olukọni, mo bẹ̀ ọ, wò ọmọ mi; nitori ọmọ mi kanṣoṣo na ni. Si kiyesi i, ẹmi èṣu a ma mu u, a si ma kigbe lojijì; a si ma nà a tàntàn titi yio fi yọ ifofó li ẹnu, a ma pa a lara, a tilẹ fẹrẹ má fi i silẹ lọ. Mo si bẹ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ lati lé e jade; nwọn kò si le ṣe e. Jesu si dahùn, wipe, Iran alaigbagbọ́ ati arekereke, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti ṣe sũru fun nyin pẹ to? Fà ọmọ rẹ wá nihinyi. Bi o si ti mbọ̀, ẹmi èṣu na gbé e ṣanlẹ, o si nà a tantan. Jesu si ba ẹmi aimọ́ na wi, o si mu ọmọ na larada, o si fà a le baba rẹ̀ lọwọ. Ẹnu si yà gbogbo wọn si iṣẹ ọlánla Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati hà si nṣe gbogbo wọn si ohun gbogbo ti Jesu ṣe, o wi fun awon ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: Ẹ jẹ ki ọrọ wọnyi ki o rì si nyin li etí: nitori a o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ. Ṣugbọn ọ̀rọ na ko yé wọn, o si ṣú wọn li oju, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ ọ: ẹ̀ru si mba wọn lati bère idi ọ̀rọ na. Iyan kan si dide lãrin wọn, niti ẹniti yio ṣe olori ninu wọn. Nigbati Jesu si mọ̀ ìro ọkàn wọn, o mu ọmọde kan, o gbé e joko lọdọ rẹ̀, O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba gbà ọmọde yi nitori orukọ mi, o gbà mi: ati ẹnikẹni ti o ba gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi: nitori ẹniti o ba kere ju ninu gbogbo nyin, on na ni yio pọ̀.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ