Luk 9:18-27

Luk 9:18-27 YBCV

O si ṣe, nigbati o kù on nikan, o ngbadura, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wà lọdọ rẹ̀: o si bi wọn pe, Tali awọn enia nfi emi pè? Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti; ṣugbọn ẹlomiran ni, Elijah ni; ati awọn ẹlomiran wipe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde. O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi emi ipè? Peteru si dahùn, wipe, Kristi ti Ọlọrun. O si kìlọ fun wọn, o si paṣẹ fun wọn, pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun na fun ẹnikan. O si wipe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati lati ọdọ awọn olori alufa, ati lati ọdọ awọn akọwe wá, a o si pa a, ni ijọ kẹta a o si ji i dide. O si wi fun gbogbo wọn pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati mã tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ́ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀ ni ijọ gbogbo, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on na ni yio si gbà a là. Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ara rẹ̀ nù, tabi ki o fi ara rẹ̀ ṣòfò. Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, oju rẹ̀ li Ọmọ-enia yio si tì, nigbati o ba de inu ogo tirẹ̀, ati ti baba rẹ̀, ati ti awọn angẹli mimọ́. Ṣugbọn emi wi fun nyin nitõtọ, ẹlomiran duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri ijọba Ọlọrun.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Luk 9:18-27

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa