Luk 6:27-38

Luk 6:27-38 YBCV

Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin. Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin. Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu. Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère. Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu. Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn. Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ. Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu. Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu. Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin: Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin.

Verse Images for Luk 6:27-38

Luk 6:27-38 - Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin.
Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin.
Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu.
Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère.
Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu.
Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn.
Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ.
Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada.
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.
Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.

Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin:
Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin.Luk 6:27-38 - Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin.
Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin.
Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu.
Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère.
Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu.
Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn.
Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ.
Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada.
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu.
Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu.

Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin:
Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa