Jesu si fi agbara Ẹmí pada wá si Galili: okikí rẹ̀ si kàn kalẹ ni gbogbo àgbegbe ti o yiká. O si nkọni ninu sinagogu wọn; a nyìn i logo lati ọdọ gbogbo awọn enia wá. O si wá si Nasareti, nibiti a gbé ti tọ́ ọ dàgba: bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si wọ̀ inu sinagogu lọ li ọjọ isimi, o si dide lati kàwe. A si fi iwe woli Isaiah fun u. Nigbati o si ṣí iwe na, o ri ibiti a gbé kọ ọ pe, Ẹmi Oluwa mbẹ lara mi, nitoriti o fi àmi oróro yàn mi lati wasu ihinrere fun awọn òtoṣi; o ti rán mi wá lati ṣe iwosan awọn ọkàn onirobinujẹ, lati wasu idasilẹ fun awọn igbekun, itunriran fun awọn afọju, ati lati jọwọ awọn ti a pa lara lọwọ. Lati kede ọdún itẹwọgba Oluwa. O si pa iwe na de, o tun fi i fun iranṣẹ, o si joko. Gbogbo awọn ti o mbẹ ninu sinagogu si tẹjumọ ọ. O si bẹ̀rẹ si iwi fun wọn pe, Loni ni Iwe-mimọ yi ṣẹ li etí nyin. Gbogbo wọn si jẹri rẹ̀, ha si ṣe wọn si ọ̀rọ ore-ọfẹ ti njade li ẹnu rẹ̀. Nwọn si wipe, Ọmọ Josefu kọ́ yi?
Kà Luk 4
Feti si Luk 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 4:14-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò