Ṣugbọn àiya fò wọn, nwọn si dijì, nwọn ṣebi awọn rí iwin. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ara nyin kò lelẹ̀? ẽsitiṣe ti ìrokuro fi nsọ ninu ọkàn nyin? Ẹ wò ọwọ́ mi ati ẹsẹ mi, pe emi tikarami ni: ẹ dì mi mu ki ẹ wò o; nitoriti iwin kò li ẹran on egungun lara, bi ẹnyin ti ri ti mo ni. Nigbati o si wi bẹ̃ tán, o fi ọwọ́ on ẹsẹ rẹ̀ hàn wọn. Nigbati nwọn kò si tí igbagbọ́ fun ayọ̀, ati fun iyanu, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ni ohunkohun jijẹ nihinyi? Nwọn si fun u li ẹja bibu, ati afára oyin diẹ. O si gba a, o jẹ ẹ loju wọn.
Kà Luk 24
Feti si Luk 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 24:37-43
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò