O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia: Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu. Bẹ̃ni on li awa ti ni ireti pe, on ni iba da Israeli ni ìde. Ati pẹlu gbogbo nkan wọnyi, oni li o di ijọ kẹta ti nkan wọnyi ti ṣẹ. Awọn obinrin kan pẹlu li ẹgbẹ wa, ti nwọn lọ si ibojì ni kutukutu, si wá idá wa nijì; Nigbati nwọn kò si ri okú rẹ̀, nwọn wá wipe, awọn ri iran awọn angẹli ti nwọn wipe, o wà lãye. Ati awọn kan ti nwọn wà pẹlu wa lọ si ibojì, nwọn si ri i gẹgẹ bi awọn obinrin ti wi: ṣugbọn on tikararẹ̀ ni nwọn kò ri. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oyé ko yé, ti o si yigbì li àiya lati gbà gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ́: Ko ha yẹ ki Kristi ki o jìya nkan wọnyi ki o si wọ̀ inu ogo rẹ̀ lọ? O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀.
Kà Luk 24
Feti si Luk 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 24:19-27
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò