Luk 24:13-35

Luk 24:13-35 YBCV

Si kiyesi i, awọn meji ninu wọn nlọ ni ijọ na si iletò kan ti a npè ni Emmausi, ti o jina si Jerusalemu niwọn ọgọta furlongi. Nwọn mba ara wọn sọ̀rọ gbogbo nkan wọnyi ti o ṣẹlẹ̀. O si ṣe, nigbati nwọn mba ara wọn sọ, ti nwọn si mba ara wọn jirorò, Jesu tikararẹ̀ sunmọ wọn, o si mba wọn rìn lọ. Ṣugbọn a rú wọn li oju ki nwọn ki o máṣe le mọ̀ ọ. O si bi wọn pe, Ọ̀rọ kili ẹnyin mba ara nyin sọ, bi ẹnyin ti nrìn? Nwọn si duro jẹ, nwọn fajuro. Ọkan ninu wọn, ti a npè ni Kleopa, si dahùn wi fun u pe, Alejò ṣá ni iwọ ni Jerusalemu, ti iwọ kò si mọ̀ ohun ti o ṣe nibẹ̀ li ọjọ wọnyi? O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia: Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu. Bẹ̃ni on li awa ti ni ireti pe, on ni iba da Israeli ni ìde. Ati pẹlu gbogbo nkan wọnyi, oni li o di ijọ kẹta ti nkan wọnyi ti ṣẹ. Awọn obinrin kan pẹlu li ẹgbẹ wa, ti nwọn lọ si ibojì ni kutukutu, si wá idá wa nijì; Nigbati nwọn kò si ri okú rẹ̀, nwọn wá wipe, awọn ri iran awọn angẹli ti nwọn wipe, o wà lãye. Ati awọn kan ti nwọn wà pẹlu wa lọ si ibojì, nwọn si ri i gẹgẹ bi awọn obinrin ti wi: ṣugbọn on tikararẹ̀ ni nwọn kò ri. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti oyé ko yé, ti o si yigbì li àiya lati gbà gbogbo eyi ti awọn woli ti wi gbọ́: Ko ha yẹ ki Kristi ki o jìya nkan wọnyi ki o si wọ̀ inu ogo rẹ̀ lọ? O si bẹ̀rẹ lati Mose ati gbogbo awọn woli wá, o si tumọ̀ nkan fun wọn ninu iwe-mimọ gbogbo nipa ti ara rẹ̀. Nwọn si sunmọ iletò ti nwọn nlọ: o si ṣe bi ẹnipe yio lọ si iwaju. Nwọn si rọ̀ ọ, wipe, Ba wa duro: nitori o di ọjọ alẹ, ọjọ si kọja tan. O si wọle lọ, o ba wọn duro. O si ṣe, bi o ti ba wọn joko tì onjẹ, o mu àkara, o sure si i, o si bù u, o si fifun wọn. Oju wọn si là, nwọn si mọ̀ ọ; o si nù mọ wọn li oju. Nwọn si ba ara wọn sọ pe, Ọkàn wa kò ha gbiná ninu wa, nigbati o mba wa sọ̀rọ li ọna, ati nigbati o ntumọ̀ iwe-mimọ́ fun wa? Nwọn si dide ni wakati kanna, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si ba awọn mọkanla pejọ, ati awọn ti mbẹ lọdọ wọn, Nwipe, Oluwa jinde nitõtọ, o si ti fi ara hàn fun Simoni. Nwọn si ròhin nkan ti o ṣe li ọ̀na, ati bi o ti di mimọ̀ fun wọn ni bibu àkara.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa