Ni ijọ kini ọ̀sẹ, ni kutukutu owurọ̀, nwọn wá si ibojì, nwọn nmu turari wá ti nwọn ti pèse silẹ, ati awọn miran kan pẹlu wọn.
Nwọn si ba a, a ti yi okuta kuro li ẹnu ibojì.
Nigbati nwọn wọ̀ inu rẹ̀, nwọn kò si ri okú Jesu Oluwa.
O si ṣe, bi nwọn ti nṣe rọunrọ̀un kiri niha ibẹ̀, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ didan duro tì wọn:
Nigbati ẹ̀ru mbà wọn, ti nwọn si dojubolẹ, awọn angẹli na bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alãye lãrin awọn okú?
Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili,
Pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹsẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde.
Nwọn si ranti ọ̀rọ rẹ̀.
Nwọn si pada ti ibojì wá, nwọn si ròhin gbogbo nkan wọnyi fun awọn mọkanla, ati fun gbogbo awọn iyokù.
Maria Magdalene, ati Joanna, ati Maria, iya Jakọbu, ati awọn omiran pẹlu wọn si ni, ti nwọn ròhin nkan wọnyi fun awọn aposteli.
Ọ̀rọ wọnyi si dabi isọkusọ loju wọn, nwọn kò si gbà wọn gbọ́.
Nigbana ni Peteru dide, o sure lọ si ibojì; nigbati o si bẹ̀rẹ, o ri aṣọ àla li ọ̀tọ fun ara wọn, o si pada lọ ile rẹ̀, ẹnu yà a si ohun ti o ṣe.