Luk 22:7-65

Luk 22:7-65 YBCV

Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja. O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile? O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀. Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ. Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ. Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya: Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun. O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin. Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de. O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili. Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn! Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi. Ijà kan si mbẹ larin wọn, niti ẹniti a kà si olori ninu wọn. O si wi fun wọn pe, Awọn ọba Keferi a ma fẹla lori wọn: a si ma pè awọn alaṣẹ wọn ni olõre. Ṣugbọn ẹnyin kì yio ri bẹ̃: ṣugbọn ẹniti o ba pọ̀ju ninu nyin ki o jẹ bi aburo; ẹniti o si ṣe olori, bi ẹniti nṣe iranṣẹ. Nitori tali o pọ̀ju, ẹniti o joko tì onjẹ, tabi ẹniti o nṣe iranṣẹ? ẹniti o joko tì onjẹ ha kọ́? ṣugbọn emi mbẹ larin nyin bi ẹniti nṣe iranṣẹ. Ẹnyin li awọn ti o ti duro tì mi ninu idanwo mi. Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi; Ki ẹnyin ki o le mã jẹ, ki ẹnyin ki o si le mã mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori itẹ́, ati ki ẹnyin ki o le mã ṣe idajọ fun awọn ẹ̀ya Israeli mejila. Oluwa si wipe, Simoni, Simoni, sawõ, Satani fẹ lati ni ọ, ki o le kù ọ bi alikama: Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le. O si wi fun u pe, Oluwa, mo mura tan lati bá ọ lọ sinu tubu, ati si ikú. O si wipe, Mo wi fun ọ, Peteru, akukọ ki yio kọ loni ti iwọ o fi sẹ́ mi li ẹrinmẹta pe, iwọ kò mọ̀ mi. O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ṣugbọn nisisiyi, ẹniti o ba li asuwọn, ki o mu u, ati àpo pẹlu: ẹniti kò ba si ni idà, ki o tà aṣọ rẹ̀, ki o si fi rà kan. Nitori mo wi fun nyin pe, Eyi ti a ti kọwe rẹ̀ kò le ṣe ki o má ṣẹ lara mi, A si kà a mọ awọn arufin. Nitori ohun wọnni nipa ti emi o li opin. Nwọn si wipe, Oluwa, sawõ, idà meji mbẹ nihinyi. O si wi fun wọn pe, O to. Ó si jade, o si lọ bi iṣe rẹ̀ si òke Olifi; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tọ̀ ọ lẹhin. Nigbati o wà nibẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ sinu idẹwò. O si fi wọn silẹ niwọn isọko kan, o si kunlẹ o si ngbadura, Wipe, Baba, bi iwọ ba fẹ, gbà ago yi lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. Angẹli kan si yọ si i lati ọrun wá, o ngbà a ni iyanju. Bi o si ti wà ni iwaya-ija o ngbadura si i kikankikan: õgùn rẹ̀ si dabi iro ẹ̀jẹ nla, o nkán silẹ. Nigbati o si dide kuro ni ibi adura, ti o si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o ba wọn, nwọn nsùn fun ibanujẹ, O si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nsùn si? ẹ dide, ẹ mã gbadura, ki ẹnyin ki o máṣe bọ́ sinu idẹwò. Bi o si ti nsọ lọwọ, kiyesi i, ọ̀pọ enia, ati ẹniti a npè ni Judasi, ọkan ninu awọn mejila, o ṣaju wọn o sunmọ Jesu lati fi ẹnu kò o li ẹnu. Jesu si wi fun u pe, Judasi, iwọ fi ifẹnukonu fi Ọmọ-enia hàn? Nigbati awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ ri bi yio ti jasi, nwọn bi i pe, Oluwa, ki awa ki o fi idà ṣá wọn? Ọkan ninu wọn si fi idà ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtún rẹ̀ sọnù. Ṣugbọn Jesu dahùn o wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ bayi na. O si fi ọwọ́ tọ́ ọ li etí, o si wò o sàn. Jesu si wi fun awọn olori alufa, ati awọn olori ẹṣọ́ tẹmpili, ati awọn agbagba, ti nwọn jade tọ̀ ọ wá, pe, Ẹnyin ha jade wá ti ẹnyin ti idà ati ọgọ bi ẹni tọ ọlọṣa wá? Nigbati emi wà pẹlu nyin lojojumọ ni tẹmpili, ẹnyin ko nà ọwọ́ mu mi: ṣugbọn akokò ti nyin li eyi, ati agbara òkunkun. Nwọn si gbá a mu, nwọn si fà a lọ, nwọn si mu u wá si ile olori alufa. Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ lẹhin li òkere. Nigbati nwọn si ti dana larin gbọ̀ngan, ti nwọn si joko pọ̀, Peteru joko larin wọn. Ọmọbinrin kan si ri i bi o ti joko nibi imọlẹ iná na, o si tẹjumọ́ ọ, o ni, Eleyi na wà pẹlu rẹ̀. O si sẹ́, o wipe, Obinrin yi, emi ko mọ̀ ọ. Kò pẹ lẹhin na ẹlomiran si ri i, o ni, Iwọ pẹlu wà ninu wọn. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, Emi kọ. O si to iwọn wakati kan ẹlomiran gidigidi tẹnumọ́ ọ, nwipe, Nitõtọ eleyi na wà pẹlu rẹ̀: nitori ara Galili ni iṣe. Ṣugbọn Peteru wipe, ọkunrin yi, emi kò mọ̀ ohun ti iwọ nwi. Lojukanna, bi o ti nwi li ẹnu, akukọ kọ. Oluwa si yipada, o wò Peteru. Peteru si ranti ọ̀rọ Oluwa, bi o ti wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ, iwọ o sẹ́ mi li ẹrinmẹta. Peteru si bọ si ode, o sọkun kikorò. Awọn ọkunrin ti nwọn mu Jesu, si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn lù u. Nigbati nwọn si dì i loju, nwọn lù u niwaju, nwọn mbi i pe, Sọtẹlẹ, tani lù ọ nì? Ati nkan pipọ miran ni nwọn nfi ọ̀rọ-òdi sọ si i.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa