Luk 22:7-23

Luk 22:7-23 YBCV

Ọjọ aiwukara pé, nigbati nwọn kò le ṣe aiṣẹbọ irekọja. O si rán Peteru on Johanu, wipe, Ẹ lọ ipèse irekọja fun wa, ki awa ki o jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a pèse sile? O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ilu lọ, ọkunrin kan ti o rù iṣa omi yio pade nyin; ẹ ba a lọ si ile ti o ba wọ̀. Ki ẹ si wi fun bãle ile na pe, Olukọni wi fun ọ pe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ: nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ. Nwọn si lọ nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ. Nigbati akokò si to, o joko ati awọn aposteli pẹlu rẹ̀. O si wi fun wọn pe, Tinu-tinu li emi fẹ fi ba nyin jẹ irekọja yi, ki emi ki o to jìya: Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio jẹ ninu rẹ̀ mọ́, titi a o fi mú u ṣẹ ni ijọba Ọlọrun. O si gbà ago, nigbati o si ti dupẹ, o wipe, Gbà eyi, ki ẹ si pín i larin ara nyin. Nitori mo wi fun nyin, Emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi ijọba Ọlọrun yio fi de. O si mú akara, nigbati o si ti dupẹ o bu u, o si fifun wọn, o wipe, Eyi li ara mi ti a fifun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Bẹ̃ gẹgẹ lẹhin onjẹ alẹ, o si mu ago, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun li ẹ̀jẹ mi, ti a ta silẹ fun nyin. Ṣugbọn ẹ kiyesi i, ọwọ́ ẹniti o fi mi hàn wà pẹlu mi lori tabili. Ọmọ-enia nlọ nitõtọ bi a ti pinnu rẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na nipasẹ ẹniti a gbé ti fi i hàn! Nwọn si bẹ̀rẹ si ibère larin ara wọn, tani ninu wọn ti yio ṣe nkan yi.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa