O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti nwọn fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi tikararẹ̀ si wi ninu iwe Psalmu pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ. Njẹ bi Dafidi ba pè e li Oluwa; on ha si ti ṣe jẹ ọmọ rẹ̀? O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li etí gbogbo enia pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse; Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.
Kà Luk 20
Feti si Luk 20
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 20:41-47
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò