Ẹnu si yà Josefu ati iya rẹ̀ si nkan ti a nsọ si i wọnyi. Simeoni si sure fun wọn, o si wi fun Maria iya rẹ̀ pe, Kiyesi i, a gbé ọmọ yi kalẹ fun iṣubu ati idide ọ̀pọ enia ni Israeli; ati fun àmi ti a nsọ̀rọ òdi si; (Idà yio si gún iwọ na li ọkàn pẹlu,) ki a le fi ironu ọ̀pọ ọkàn hàn. Ẹnikan si mbẹ, Anna woli, ọmọbinrin Fanueli, li ẹ̀ya Aseri: ọjọ ogbó rẹ̀ pọ̀, o ti ba ọkọ gbé li ọdún meje lati igba wundia rẹ̀ wá; O si ṣe opó ìwọn ọdún mẹrinlelọgọrin, ẹniti kò kuro ni tẹmpili, o si nfi àwẹ ati adura sìn Ọlọrun lọsán ati loru. O si wọle li akokò na, o si dupẹ fun Oluwa pẹlu, o si sọ̀rọ rẹ̀ fun gbogbo awọn ti o nreti idande Jerusalemu. Nigbati nwọn si ti ṣe nkan gbogbo tan gẹgẹ bi ofin Oluwa, nwọn pada lọ si Galili, si Nasareti ilu wọn. Ọmọ na si ndàgba, o si nlagbara, o si kún fun ọgbọn: ore-ọfẹ Ọlọrun si mbẹ lara rẹ̀.
Kà Luk 2
Feti si Luk 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 2:33-40
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò