Luk 2:15-26

Luk 2:15-26 YBCV

O si ṣe, nigbati awọn angẹli na pada kuro lọdọ wọn lọ si ọrun, awọn ọkunrin oluṣọ-agutan na ba ara wọn sọ pe, Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Betlehemu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa. Nwọn si wá lọgan, nwọn si ri Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wá. Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ́, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀. Awọn oluṣọ-agutan si pada lọ, nwọn nfi ogo fun Ọlọrun, nwọn si nyìn i, nitori ohun gbogbo ti nwọn ti gbọ́ ati ti nwọn ti ri, bi a ti wi i fun wọn. Nigbati ijọ mẹjọ si pé lati kọ ọmọ na nila, nwọn pè orukọ rẹ̀ ni JESU, bi a ti sọ ọ tẹlẹ lati ọdọ angẹli na wá ki a to lóyun rẹ̀ ninu. Nigbati ọjọ iwẹnu Maria si pé gẹgẹ bi ofin Mose, nwọn gbé Jesu wá si Jerusalemu lati fi i fun Oluwa; (Bi a ti kọ ọ sinu ofin Oluwa pe, Gbogbo ọmọ ọkunrin ti o ṣe akọbi, on li a o pè ni mimọ́ fun Oluwa;) Ati lati rubọ gẹgẹ bi eyi ti a wi ninu ofin Oluwa, Àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ni Jerusalemu, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Simeoni; ọkunrin na si ṣe olõtọ ati olufọkànsin, o nreti itunu Israeli: Ẹmí Mimọ́ si bà le e. A si ti fihàn a lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ na wá pe, on kì yio ri ikú, ki o to ri Kristi Oluwa.