Luk 2:1-20

Luk 2:1-20 YBCV

O SI ṣe li ọjọ wọnni, aṣẹ ti ọdọ Kesari Augustu jade wá pe, ki a kọ orukọ gbogbo aiye sinu iwe. (Eyi ni ikọsinu-iwe ikini ti a ṣe nigbati Kireniu fi jẹ Bãlẹ Siria.) Gbogbo awọn enia si lọ lati kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe, olukuluku si ilu ara rẹ̀. Josefu pẹlu si goke lati Nasareti ilu Galili lọ, si ilu Dafidi ni Judea, ti a npè ni Betlehemu; nitoriti iran ati idile Dafidi ni iṣe, Lati kọ orukọ rẹ̀, pẹlu Maria aya rẹ̀ afẹsọna, ti o tobi fun oyún. O si ṣe, nigbati nwọn wà nibẹ̀, ọjọ rẹ̀ pé ti on o bí. O si bí akọbi rẹ̀ ọmọkunrin, o si fi ọja wé e, o si tẹ́ ẹ sinu ibujẹ ẹran; nitoriti àye kò si fun wọn ninu ile èro. Awọn oluṣọ-agutan mbẹ ni ilu na, nwọn nṣọ agbo agutan wọn li oru ni pápá ti nwọn ngbé. Sá si kiyesi i, angẹli Oluwa na yọ si wọn, ogo Oluwa si ràn yi wọn ká: ẹ̀ru si ba wọn gidigidi. Angẹli na si wi fun wọn pe, Má bẹ̀ru: sawò o, mo mu ihinrere ayọ̀ nla fun nyin wá, ti yio ṣe ti enia gbogbo. Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa. Eyi ni yio si ṣe àmi fun nyin; ẹnyin ó ri ọmọ-ọwọ ti a fi ọja wé, o dubulẹ ni ibujẹ ẹran. Ọpọlọpọ ogun ọrun si yọ si angẹli na li ojijì, nwọn nyìn Ọlọrun, wipe, Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia. O si ṣe, nigbati awọn angẹli na pada kuro lọdọ wọn lọ si ọrun, awọn ọkunrin oluṣọ-agutan na ba ara wọn sọ pe, Ẹ jẹ ki a lọ tàra si Betlehemu, ki a le ri ohun ti o ṣẹ, ti Oluwa fihàn fun wa. Nwọn si wá lọgan, nwọn si ri Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wá. Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ́, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀. Awọn oluṣọ-agutan si pada lọ, nwọn nfi ogo fun Ọlọrun, nwọn si nyìn i, nitori ohun gbogbo ti nwọn ti gbọ́ ati ti nwọn ti ri, bi a ti wi i fun wọn.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Luk 2:1-20

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa