Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o lọ ṣaju, o ngòke lọ si Jerusalemu.
O si ṣe, nigbati o sunmọ Betfage on Betaní li òke ti a npè ni Olifi, o rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,
Wipe, Ẹ lọ iletò ti o kọju si nyin; nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ọ lọ, ẹnyin o ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn ri: ẹ tú u, ki ẹ si fà a wá.
Bi ẹnikẹni ba si bi nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú u? ki ẹnyin ki o wi bayi pe, Oluwa ni ifi i ṣe.
Awọn ti a rán si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.
Bi nwọn si ti ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, awọn oluwa rẹ̀ bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú kẹtẹkẹtẹ nì?
Nwọn si wipe, Oluwa ni ifi i ṣe.
Nwọn si fà a tọ̀ Jesu wá: nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, nwọn si gbé Jesu kà a.
Bi o si ti nlọ nwọn tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na.
Bi o si ti sunmọ eti ibẹ̀ ni gẹrẹgẹrẹ òke Olifi, gbogbo ijọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si iyọ̀, ati si ifi ohùn rara yìn Ọlọrun, nitori iṣẹ nla gbogbo ti nwọn ti ri;
Wipe, Olubukun li Ọba ti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: alafia li ọrun, ati ogo loke ọrun.
Awọn kan ninu awọn Farisi li awujọ si wi fun u pe, Olukọni ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi.
O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke.
Nigbati o si sunmọ etile, o ṣijuwò ilu na, o sọkun si i lori,
O nwipe, Ibaṣepe iwọ mọ̀, loni yi, ani iwọ, ohun ti iṣe ti alafia rẹ! ṣugbọn nisisiyi nwọn pamọ́ kuro li oju rẹ.
Nitori ọjọ mbọ̀ fun ọ, ti awọn ọtá rẹ yio wà yàra ká ọ, nwọn o si yi ọ ká, nwọn o si ká ọ mọ́ niha gbogbo.
Nwọn o si wó ọ palẹ bẹrẹ, ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; nwọn kì yio si fi okuta kan silẹ lori ara wọn; nitoriti iwọ ko mọ̀ ọjọ ìbẹwo rẹ.