Luk 19:28-41

Luk 19:28-41 YBCV

Nigbati o si wi nkan wọnyi tan, o lọ ṣaju, o ngòke lọ si Jerusalemu. O si ṣe, nigbati o sunmọ Betfage on Betaní li òke ti a npè ni Olifi, o rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Wipe, Ẹ lọ iletò ti o kọju si nyin; nigbati ẹnyin ba nwọ̀ ọ lọ, ẹnyin o ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn ri: ẹ tú u, ki ẹ si fà a wá. Bi ẹnikẹni ba si bi nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú u? ki ẹnyin ki o wi bayi pe, Oluwa ni ifi i ṣe. Awọn ti a rán si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn si bá a gẹgẹ bi o ti wi fun wọn. Bi nwọn si ti ntú ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, awọn oluwa rẹ̀ bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ntú kẹtẹkẹtẹ nì? Nwọn si wipe, Oluwa ni ifi i ṣe. Nwọn si fà a tọ̀ Jesu wá: nwọn si tẹ́ aṣọ wọn si ẹ̀hin ọmọ kẹtẹkẹtẹ na, nwọn si gbé Jesu kà a. Bi o si ti nlọ nwọn tẹ́ aṣọ wọn si ọ̀na. Bi o si ti sunmọ eti ibẹ̀ ni gẹrẹgẹrẹ òke Olifi, gbogbo ijọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bẹ̀rẹ si iyọ̀, ati si ifi ohùn rara yìn Ọlọrun, nitori iṣẹ nla gbogbo ti nwọn ti ri; Wipe, Olubukun li Ọba ti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: alafia li ọrun, ati ogo loke ọrun. Awọn kan ninu awọn Farisi li awujọ si wi fun u pe, Olukọni ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi. O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke. Nigbati o si sunmọ etile, o ṣijuwò ilu na, o sọkun si i lori

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Luk 19:28-41