O si pa owe yi fun awọn kan ti nwọn gbẹkẹle ara wọn pe, awọn li olododo, ti nwọn si ngàn awọn ẹlomiran: Pe, Awọn ọkunrin meji goke lọ si tẹmpili lati gbadura; ọkan jẹ Farisi, ekeji si jẹ agbowode. Eyi Farisi dide, o si ngbadura ninu ara rẹ̀ bayi pe, Ọlọrun, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti emi kò ri bi awọn ara iyokù, awọn alọnilọwọgba, alaiṣõtọ, panṣaga, tabi emi kò tilẹ ri bi agbowode yi. Emi ngbàwẹ li ẹrinmeji li ọ̀sẹ, mo nsan idamẹwa ohun gbogbo ti mo ni. Ṣugbọn agbowode duro li òkere, kò tilẹ jẹ gbé oju rẹ̀ soke ọrun, ṣugbọn o lù ara rẹ̀ li õkan-àiya, o wipe, Ọlọrun ṣãnu fun mi, emi ẹlẹṣẹ. Mo wi fun nyin, ọkunrin yi sọkalẹ lọ si ile rẹ̀ ni idalare jù ekeji lọ: nitori ẹnikẹni ti o ba gbé ara rẹ̀ ga, on li a o rẹ̀ silẹ; ẹniti o ba si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ on li a o gbéga.
Kà Luk 18
Feti si Luk 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 18:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò