Nigbati Jesu si gbọ́ eyi, o wi fun u pe, Ohun kan li o kù fun ọ sibẹ: lọ ità ohun gbogbo ti o ni, ki o si pín i fun awọn talakà, iwọ o si ni iṣura li ọrun: si wá, ki o mã tọ̀ mi lẹhin. Nigbati o si gbọ́ eyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi: nitoriti o li ọrọ̀ pipo. Nigbati Jesu ri i pe, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi, o ni, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! Nitori o rọrun fun ibakasiẹ lati gbà oju abẹrẹ wọle, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. Awọn ti o si gbọ́ wipe, Njẹ tali o ha le là? O si wipe, Ohun ti o ṣoro lọdọ enia, kò ṣoro lọdọ Ọlọrun. Peteru si wipe, Sawõ, awa ti fi tiwa silẹ, a si tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile, tabi aya, tabi ará, tabi õbi, tabi ọmọ silẹ, nitori ijọba Ọlọrun, Ti kì yio gba ilọpo pipọ si i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun.
Kà Luk 18
Feti si Luk 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 18:22-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò