GBOGBO awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ si sunmọ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀. Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun. O si pa owe yi fun wọn, wipe. Ọkunrin wo ni ninu nyin, ti o ni ọgọrun agutan, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, ti kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ ni iju, ti kì yio si tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yio fi ri i? Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ. Nigbati o si de ile, o pè awọn ọrẹ́ ati aladugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, Ẹ ba mi yọ̀; nitoriti mo ri agutan mi ti o ti nù. Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, jù lori olõtọ mọkandilọgọrun lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada. Tabi obinrin wo li o ni fadaka mẹwa bi o ba sọ ọkan nù, ti kì yio tàn fitilà, ki o si gbá ile, ki o si wá a gidigidi titi yio fi ri i? Nigbati o si ri i, o pè awọn ọrẹ́ ati awọn aladugbo rẹ̀ jọ, o wipe, Ẹ ba mi yọ̀; nitori mo ri fadakà ti mo ti sọnù. Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ mbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada.
Kà Luk 15
Feti si Luk 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 15:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò