Luk 15

15
Òwe Nípa Agutan tí Ó Sọnù
(Mat 18:12-14)
1GBOGBO awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ si sunmọ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀.
2Ati awọn Farisi ati awọn akọwe nkùn, wipe, ọkunrin yi ngbà ẹlẹṣẹ, o si mba wọn jẹun.
3O si pa owe yi fun wọn, wipe.
4 Ọkunrin wo ni ninu nyin, ti o ni ọgọrun agutan, bi o ba sọ ọ̀kan nù ninu wọn, ti kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ ni iju, ti kì yio si tọsẹ eyi ti o nù lọ, titi yio fi ri i?
5 Nigbati o si ri i tan, o gbé e le ejika rẹ̀, o nyọ.
6 Nigbati o si de ile, o pè awọn ọrẹ́ ati aladugbo rẹ̀ jọ, o nwi fun wọn pe, Ẹ ba mi yọ̀; nitoriti mo ri agutan mi ti o ti nù.
7 Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ yio wà li ọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, jù lori olõtọ mọkandilọgọrun lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada.
Òwe Nípa Fàdákà tí Ó Sọnù
8 Tabi obinrin wo li o ni fadaka mẹwa bi o ba sọ ọkan nù, ti kì yio tàn fitilà, ki o si gbá ile, ki o si wá a gidigidi titi yio fi ri i?
9 Nigbati o si ri i, o pè awọn ọrẹ́ ati awọn aladugbo rẹ̀ jọ, o wipe, Ẹ ba mi yọ̀; nitori mo ri fadakà ti mo ti sọnù.
10 Mo wi fun nyin, gẹgẹ bẹ̃li ayọ̀ mbẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada.
Òwe Nípa Ọmọ tí Ó Sọnù
11O si wipe, Ọkunrin kan li ọmọkunrin meji:
12 Eyi aburo ninu wọn wi fun baba rẹ̀ pe, Baba, fun mi ni ini rẹ ti o kàn mi. O si pín ohun ìni rẹ̀ fun wọn.
13 Kò si to ijọ melokan lẹhinna, eyi aburo kó ohun gbogbo ti o ni jọ, o si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n lọ si ilẹ òkere, nibẹ̀ li o si gbé fi ìwa wọ̀bia na ohun ini rẹ̀ ni inákuna.
14 Nigbati o si bà gbogbo rẹ̀ jẹ tan, ìyan nla wá imu ni ilẹ na; o si bẹ̀rẹ si idi alaini.
15 O si lọ, o da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ọlọ̀tọ kan ni ilẹ na; on si rán a lọ si oko rẹ̀ lati tọju ẹlẹdẹ.
16 Ayọ̀ ni iba fi jẹ onjẹ ti awọn ẹlẹdẹ njẹ li ajẹyó: ẹnikẹni kò si fifun u.
17 Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin.
18 Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ;
19 Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ.
20 O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.
21 Ọmọ na si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ, emi kò yẹ li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́.
22 Ṣugbọn baba na wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Ẹ mu ãyo aṣọ wá kánkán, ki ẹ si fi wọ̀ ọ; ẹ si fi oruka bọ̀ ọ lọwọ, ati bàta si ẹsẹ rẹ̀:
23 Ẹ si mu ẹgbọ̀rọ malu abọpa wá, ki ẹ si pa a; ki a mã jẹ, ki a si mã ṣe ariya:
24 Nitori ọmọ mi yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i. Nwọn si bẹ̀re si iṣe ariya.
25 Ṣugbọn ọmọ rẹ̀ eyi ẹgbọn ti wà li oko: bi o si ti mbọ̀, ti o sunmọ eti ile, o gbọ́ orin on ijó.
26 O si pè ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ wọn, o bère, kili ã mọ̀ nkan wọnyi si?
27 O si wi fun u pe, Aburo rẹ de; baba rẹ si pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa, nitoriti o ri i pada li alafia ati ni ilera.
28 O si binu, o si kọ̀ lati wọle; baba rẹ̀ si jade, o si wá iṣipẹ fun u.
29 O si dahùn o wi fun baba rẹ̀ pe, Wo o, lati ọdún melo wọnyi li emi ti nsin ọ, emi kò si ru ofin rẹ ri: iwọ kò si ti ifi ọmọ ewurẹ kan fun mi, lati fi ba awọn ọrẹ́ mi ṣe ariya:
30 Ṣugbọn nigbati ọmọ rẹ yi de, ẹniti o fi panṣaga run ọrọ̀ rẹ, iwọ si ti pa ẹgbọ̀rọ malu abọpa fun u.
31 O si wi fun u pe, Ọmọ, nigbagbogbo ni iwọ mbẹ lọdọ mi, ohun gbogbo ti mo si ni, tìrẹ ni.
32 O yẹ ki a ṣe ariya ki a si yọ̀: nitori aburo rẹ yi ti kú, o si tún yè; o ti nù, a si ri i.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Luk 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀