Awọn ọpọ ijọ enia mba a lọ: o si yipada, o si wi fun wọn pe,
Bi ẹnikan ba tọ̀ mi wá, ti ko si korira baba rẹ̀, ati iya, ati aya, ati ọmọ, ati arakunrin, ati arabinrin, ani ati ẹmí ara rẹ̀ pẹlu, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.
Ẹnikẹni ti kò ba rù agbelebu rẹ̀, ki o si ma tọ̀ mi lẹhin, kò le ṣe ọmọ-ẹhin mi.
Nitori tani ninu nyin ti npete ati kọ́ ile-iṣọ, ti kì yio kọ́ joko ki o ṣiro iye owo rẹ̀, bi on ni to ti yio fi pari rẹ̀.
Ki o ma ba jẹ pe nigbati o ba fi ipilẹ ile sọlẹ tan, ti kò le pari rẹ̀ mọ́, gbogbo awọn ti o ri i a bẹ̀rẹ si ifi i ṣe ẹlẹyà,
Wipe, ọkunrin yi bẹ̀rẹ si ile ikọ́, kò si le pari rẹ̀.
Tabi ọba wo ni nlọ ibá ọba miran jà, ti kì yio kọ́ joko, ki o si gbèro bi yio le fi ẹgbarun padegun ẹniti nmu ẹgbawa bọ̀ wá kò on loju?
Bi bẹ̃kọ nigbati onitọhun si wà li òkere, on a ran ikọ si i, a si bere ipinhùn alafia.
Gẹgẹ bẹ̃ni, ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin, ti kò ba kò ohun gbogbo ti o ni silẹ, kọ̀ le ṣe ọmọ-ẹhin mi.