Luk 13:1-17

Luk 13:1-17 YBCV

AWỌN kan si wà li akokò na ti o sọ ti awọn ara Galili fun u, ẹ̀jẹ ẹniti Pilatu dàpọ mọ ẹbọ wọn. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣebi awọn ara Galili wọnyi ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn ara Galili lọ, nitoriti nwọn jẹ irú ìya bawọnni? Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ? Mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ: bikoṣepe ẹnyin ronupiwada, gbogbo nyin ni yio ṣegbé bẹ̃ gẹgẹ. O si pa owe yi fun wọn pe: Ọkunrin kan ni igi ọpọtọ kan ti a gbìn si ọgbà ajara rẹ̀; o si de, o nwá eso lori rẹ̀, kò si ri nkan. O si wi fun oluṣọgba rẹ̀ pe, Sawõ, lati ọdún mẹta li emi ti nwá iwò eso lori igi ọpọtọ yi, emi ko si ri nkan: ké e lulẹ; ẽṣe ti o fi ngbilẹ lasan pẹlu? O si dahùn o wi fun u pe, Oluwa, jọwọ rẹ̀ li ọdún yi pẹlu, titi emi o fi tú ilẹ idi rẹ̀ yiká, titi emi o si fi bu ilẹdu si i: Bi o ba si so eso, gẹgẹ: bi kò ba si so, njẹ lẹhin eyini ki iwọ ki o ke e lulẹ̀. O si nkọ́ni ninu sinagogu kan li ọjọ isimi. Si kiyesi i, obinrin kan wà nibẹ̀ ti o ni ẹmí ailera, lati ọdún mejidilogun wá, ẹniti o tẹ̀ tan, ti ko le gbé ara rẹ̀ soke bi o ti wù ki o ṣe. Nigbati Jesu ri i, o pè e si ọdọ, o si wi fun u pe, Obinrin yi, a tú ọ silẹ lọwọ ailera rẹ. O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo. Olori sinagogu si kun fun irunu, nitoriti Jesu muni larada li ọjọ isimi, o si wi fun ijọ enia pe, Ijọ mẹfa ni mbẹ ti a fi iṣiṣẹ: ninu wọn ni ki ẹnyin ki o wá ki a ṣe dida ara nyin, ki o máṣe li ọjọ isimi. Nigbana li Oluwa dahùn, o si wi fun u pe, Ẹnyin agabagebe, olukuluku nyin ki itú malu tabi kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ kuro nibuso, ki si ifà a lọ imu omi li ọjọ isimi? Kò si yẹ ki a tú obinrin yi ti iṣe ọmọbinrin Abrahamu silẹ ni ìde yi li ọjọ isimi, ẹniti Satani ti dè, sawõ lati ọdún mejidilogun yi wá? Nigbati o si wi nkan wọnyi, oju tì gbogbo awọn ọtá rẹ̀: gbogbo ijọ enia si yọ̀ fun ohun ogo gbogbo ti o ṣe lati ọwọ́ rẹ̀ wá.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Luk 13:1-17

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa