Mo si wi fun nyin pẹlu, Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, Ọmọ-ẹnia yio si jẹwọ rẹ̀ niwaju awọn angẹli Ọlọrun: Ṣugbọn ẹniti o ba sẹ́ mi niwaju enia, a o sẹ́ ẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun. Ati ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ-òdi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a kì yio dari rẹ̀ jì i. Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagogu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi: Nitori Ẹmí Mimọ́ yio kọ́ nyin ni wakati kanna li ohun ti o yẹ ki ẹ wi.
Kà Luk 12
Feti si Luk 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 12:8-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò