O si wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti yio ni ọrẹ́ kan, ti yio si tọ̀ ọ lọ larin ọganjọ, ti yio si wi fun u pe, Ọrẹ́, win mi ni ìṣu akara mẹta: Nitori ọrẹ́ mi kan ti àjo bọ sọdọ mi, emi kò si ni nkan ti emi o gbé kalẹ niwaju rẹ̀; Ti on o si gbé inu ile dahùn wi fun u pe, Má yọ mi lẹnu: a ti sé ilẹkun na, awọn ọmọ mi si mbẹ lori ẹní pẹlu mi; emi ko le dide fifun ọ? Mo wi fun nyin, bi on kò tilẹ fẹ dide ki o fifun u, nitoriti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nitori awiyannu rẹ̀ yio dide, yio si fun u pọ̀ to bi o ti nfẹ. Emi si wi fun nyin, Ẹ bère, a o si fifun nyin; ẹ wá kiri, ẹnyin o si ri; ẹ kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin. Nitori ẹnikẹni ti o ba bère, o ri gbà; ẹniti o si nwá kiri o ri; ati ẹniti o kànkun li a o ṣí i silẹ fun. Tani iṣe baba ninu nyin ti ọmọ rẹ̀ yio bère akara lọdọ rẹ̀, ti o jẹ fun u li okuta? tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò dipo ẹja? Tabi bi o si bère ẹyin, ti o jẹ fun u li akẽkẽ? Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu ba mọ̀ bi ãti ifi ẹ̀bun didara fun awọn ọmọ nyin: melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ fun awọn ti o mbère lọdọ rẹ̀?
Kà Luk 11
Feti si Luk 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 11:5-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò