Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ sí wipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli. Nitori bi Jona ti jẹ àmi fun awọn ara Ninefe, gẹgẹ bẹ̃ li Ọmọ-enia yio ṣe àmi fun iran yi. Ọbabirin gusù yio dide li ọjọ idajọ pẹlu awọn enia iran yi, yio si da wọn lẹbi: nitoriti o ti iha ipẹkun aiye wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi. Awọn ara Ninefe yio dide li ọjọ idajọ pẹlu iran yi, nwọn o si da a lẹbi: nitoriti nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Jona lọ mbẹ nihinyi. Kò si ẹnikan, nigbati o ba tan fitila tán, ti igbé e si ìkọkọ, tabi sabẹ oṣuwọn, bikoṣe sori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọle ba le mã ri imọlẹ. Oju ni imọlẹ ara: bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ a mọlẹ; ṣugbọn bi oju rẹ ba buru, ara rẹ pẹlu a kun fun òkunkun. Nitorina kiyesi i, ki imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ki o máṣe di òkunkun. Njẹ bi gbogbo ara rẹ ba kun fun imọlẹ, ti ko li apakan ti o ṣokunkun, ara rẹ, gbogbo ni yio kun fun imọlẹ, bi igbati fitila ba fi itanṣan rẹ̀ fun ọ ni imọlẹ. Bi o si ti nwi, Farisi kan bẹ̀ ẹ ki o ba on jẹun: o si wọle, o joko lati jẹun.
Kà Luk 11
Feti si Luk 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 11:29-37
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò