Luk 11
11
Adura Oluwa
(Mat 6:9-13; 7:7-11)
1O si ṣe, bi o ti ngbadura ni ibi kan, bi o ti dakẹ, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, kọ́ wa bi ãti igbadura, bi Johanu si ti kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
2O si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba ngbadura, ẹ mã wipe, Baba wa ti mbẹ li ọrun, Ki a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹni li aiye.
3 Fun wa li onjẹ ojọ wa li ojojumọ́.
4 Ki o si dari ẹ̀ṣẹ wa jì wa; nitori awa tikarawa pẹlu a ma darijì olukuluku ẹniti o jẹ wa ni gbese. Má si fà wa sinu idẹwò; ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi.
5O si wi fun wọn pe, Tani ninu nyin ti yio ni ọrẹ́ kan, ti yio si tọ̀ ọ lọ larin ọganjọ, ti yio si wi fun u pe, Ọrẹ́, win mi ni ìṣu akara mẹta:
6 Nitori ọrẹ́ mi kan ti àjo bọ sọdọ mi, emi kò si ni nkan ti emi o gbé kalẹ niwaju rẹ̀;
7 Ti on o si gbé inu ile dahùn wi fun u pe, Má yọ mi lẹnu: a ti sé ilẹkun na, awọn ọmọ mi si mbẹ lori ẹní pẹlu mi; emi ko le dide fifun ọ?
8 Mo wi fun nyin, bi on kò tilẹ fẹ dide ki o fifun u, nitoriti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nitori awiyannu rẹ̀ yio dide, yio si fun u pọ̀ to bi o ti nfẹ.
9 Emi si wi fun nyin, Ẹ bère, a o si fifun nyin; ẹ wá kiri, ẹnyin o si ri; ẹ kànkun, a o si ṣi i silẹ fun nyin.
10 Nitori ẹnikẹni ti o ba bère, o ri gbà; ẹniti o si nwá kiri o ri; ati ẹniti o kànkun li a o ṣí i silẹ fun.
11 Tani iṣe baba ninu nyin ti ọmọ rẹ̀ yio bère akara lọdọ rẹ̀, ti o jẹ fun u li okuta? tabi bi o bère ẹja, ti o jẹ fun u li ejò dipo ẹja?
12 Tabi bi o si bère ẹyin, ti o jẹ fun u li akẽkẽ?
13 Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu ba mọ̀ bi ãti ifi ẹ̀bun didara fun awọn ọmọ nyin: melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ fun awọn ti o mbère lọdọ rẹ̀?
Jesu ati Beelsebulu
(Mat 12:22-30; Mak 3:20-27)
14O si nlé ẹmi èṣu kan jade, ti o si yadi. O si ṣe, nigbati ẹmi èṣu na jade, odi sọrọ; ẹnu si yà ijọ enia.
15Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn wipe, Nipa Beelsebubu olori awọn ẹmi èṣu li o fi nlé awọn ẹmi èṣu jade.
16Awọn ẹlomiran si ndan a wò, nwọn fẹ àmi lọdọ rẹ̀ lati ọrun wá.
17Ṣugbọn on mọ̀ ìro inu wọn, o wi fun wọn pe, Gbogbo ijọba ti o yà ara rẹ̀ ni ipa, a sọ ọ di ahoro; ile ti o si yà ara rẹ̀ ni ipa, a wó.
18 Bi Satani si yàpa si ara rẹ̀, ijọba rẹ̀ yio ha ṣe duro? nitori ẹnyin wipe, Nipa Beelsebubu li emi fi nle awọn ẹmi èṣu jade.
19 Bi o ba si ṣepe nipa Beelsebubu li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, nipa tali awọn ọmọ nyin fi nlé wọn jade? nitorina awọn ni yio ṣe onidajọ nyin.
20 Ṣugbọn bi o ba ṣepe ika Ọlọrun li emi fi nlé awọn ẹmi èṣu jade, kò si aniani, ijọba Ọlọrun de ba nyin.
21 Nigbati ọkunrin alagbara ti o hamọra ba nṣọ afin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ a wà li alãfia:
22 Ṣugbọn nigbati ẹniti o li agbara jù u ba kọlù u, ti o si ṣẹgun rẹ̀, a gbà gbogbo ihamọra rẹ̀ ti o gbẹkẹle lọwọ rẹ̀, a si pín ikogun rẹ̀.
23 Ẹniti kò ba wà pẹlu mi, o lodi si mi: ẹniti kò ba si bá mi kopọ̀, o nfunká.
24 Nigbati ẹmi aimọ́ ba jade kuro lara enia, ama rìn kiri ni ibi gbigbẹ, ama wá ibi isimi; nigbati ko ba si ri, a wipe, Emi o pada lọ si ile mi nibiti mo gbé ti jade wá.
25 Nigbati o si de, o bá a, a gbá a, a si ṣe e li ọṣọ́.
26 Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn wọle, nwọn si joko nibẹ̀: igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ.
Ẹni Tí Ó ní Ibukun Tòótọ́
27O si ṣe, bi o ti nsọ nkan wọnyi, obinrin kan nahùn ninu ijọ, o si wi fun u pe, Ibukun ni fun inu ti o bí ọ, ati ọmú ti iwọ mu.
28Ṣugbọn on wipe, Nitõtọ, ki a kuku wipe, Ibukun ni fun awọn ti ngbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti nwọn si pa a mọ́.
Àwọn Kan Bèèrè Àmì Lọ́wọ́ Jesu
(Mat 12:38-42; Mak 8:12)
29Nigbati ijọ enia si ṣùjọ si ọdọ rẹ̀ o bẹ̀rẹ sí wipe, Iran buburu li eyi: nwọn nwá àmi; a kì yio si fi àmi kan fun u, bikoṣe àmi Jona woli.
30 Nitori bi Jona ti jẹ àmi fun awọn ara Ninefe, gẹgẹ bẹ̃ li Ọmọ-enia yio ṣe àmi fun iran yi.
31 Ọbabirin gusù yio dide li ọjọ idajọ pẹlu awọn enia iran yi, yio si da wọn lẹbi: nitoriti o ti iha ipẹkun aiye wá lati gbọ́ ọgbọ́n Solomoni: si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi.
32 Awọn ara Ninefe yio dide li ọjọ idajọ pẹlu iran yi, nwọn o si da a lẹbi: nitoriti nwọn ronupiwada nipa iwasu Jona; si kiyesi i, ẹniti o pọ̀ju Jona lọ mbẹ nihinyi.
Ìmọ́lẹ̀ Ara
(Mat 5:15; 6:22-23)
33 Kò si ẹnikan, nigbati o ba tan fitila tán, ti igbé e si ìkọkọ, tabi sabẹ oṣuwọn, bikoṣe sori ọpá fitilà, ki awọn ti nwọle ba le mã ri imọlẹ.
34 Oju ni imọlẹ ara: bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ a mọlẹ; ṣugbọn bi oju rẹ ba buru, ara rẹ pẹlu a kun fun òkunkun.
35 Nitorina kiyesi i, ki imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ki o máṣe di òkunkun.
36 Njẹ bi gbogbo ara rẹ ba kun fun imọlẹ, ti ko li apakan ti o ṣokunkun, ara rẹ, gbogbo ni yio kun fun imọlẹ, bi igbati fitila ba fi itanṣan rẹ̀ fun ọ ni imọlẹ.
Jesu Bá Àwọn Farisi ati Àwọn Akọ̀wé Wí
(Mat 23:1-36; Mak 12:38-40; Luk 20:45-47)
37Bi o si ti nwi, Farisi kan bẹ̀ ẹ ki o ba on jẹun: o si wọle, o joko lati jẹun.
38Nigbati Farisi na si ri i, ẹnu yà a nitoriti kò kọ́ wẹ̀ ki o to jẹun.
39Oluwa si wi fun u pe, Ẹnyin Farisi a ma fọ̀ ode ago ati awopọkọ́; ṣugbọn inu nyin kún fun irẹjẹ iwa-buburu.
40 Ẹnyin alaimoye, ẹniti o ṣe eyi ti mbẹ lode, on kọ́ ha ṣe eyi ti mbẹ ninu pẹlu?
41 Ki ẹnyin ki o kuku mã ṣe itọrẹ ãnu ninu ohun ti ẹnyin ni; si kiyesi i, ohun gbogbo li o di mimọ́ fun nyin.
42 Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin a ma san idamẹwa minti, ati rue, ati gbogbo ewebẹ̀, ṣugbọn ẹnyin gbojufò idajọ ati ifẹ Ọlọrun: wọnyi li ẹnyin iba ṣe, ẹ kì ba si ti fi ekeji silẹ laiṣe.
43 Egbé ni fun nyin, ẹnyin Farisi! nitoriti ẹnyin fẹ ipò-ọlá ninu sinagogu, ati ikí-ni li ọjà.
44 Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe, ati ẹnyin Farisi, agabagebe! nitoriti ẹnyin dabi isa okú ti kò hàn, awọn enia ti o si nrìn lori wọn kò mọ̀.
45Nigbana li ọkan ninu awọn amofin dahùn, o si wi fun u pe, Olukọni, li eyi ti iwọ nwi nì iwọ ngàn awa pẹlu.
46O si wipe, Egbé ni fun ẹnyin amofin pẹlu! nitoriti ẹnyin di ẹrù ti o wuwo lati rù le enia lori, bẹ̃ni ẹnyin tikara nyin kò jẹ fi ika nyin kan kàn ẹrù na.
47 Egbé ni fun nyin! nitoriti ẹnyin kọ́le oju-õrì awọn woli, awọn baba nyin li o si ti pa wọn.
48 Njẹ ẹnyin njẹ ẹlẹri, ẹ si ni inudidun si iṣe awọn baba nyin: nitori nwọn pa wọn, ẹnyin si kọ́le oju-õrì wọn.
49 Nitori eyi li ọgbọ́n Ọlọrun si ṣe wipe, emi ó rán awọn woli ati awọn aposteli si wọn, ninu wọn ni nwọn o si pa, ti nwọn o si ṣe inunibini si:
50 Ki a le bère ẹ̀jẹ awọn woli gbogbo, ti a ti ta silẹ lati igba ipilẹṣẹ aiye wá, lọdọ iran yi;
51 Lati ẹ̀jẹ Abeli wá, titi o si fi de ẹ̀jẹ Sakariah, ti o ṣegbé lãrin pẹpẹ on tẹmpili: lõtọ ni mo wi fun nyin, A o bère rẹ̀ lọdọ iran yi.
52 Egbé ni fun nyin, ẹnyin amofin! nitoriti ẹnyin gbà ọmọ-ṣika ìmọ: ẹnyin tikaranyin kò wọle, awọn ti si nwọle, li ẹnyin kọ̀ fun.
53Bi o ti nwi nkan wọnyi fun wọn, awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si ibinu si i gidigidi, nwọn si nyọ ọ́ lẹnu lati wi nkan pipọ:
54Nwọn nṣọ ọ, nwọn nwá ọ̀na ati ri nkan gbámu li ẹnu rẹ̀, ki nwọn ki o le fi i sùn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Luk 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.