Luk 10:40-42

Luk 10:40-42 YBCV

Ṣugbọn Marta nṣe iyọnu ohun pupọ, o si tọ̀ ọ wá, o ni, Oluwa, iwọ kò kuku ṣu si i ti arabinrin mi fi mi silẹ lati mã nikan ṣe aisimi? Wi fun u ki o ràn mi lọwọ. Ṣugbọn Jesu si dahùn, o si wi fun u pe, Marta, Marta, iwọ nṣe aniyan ati lãlã nitori ohun pipọ: Ṣugbọn ohun kan li a kò le ṣe alaini. Maria si ti yàn ipa rere na, ti a kò le gbà lọwọ rẹ̀.

Àwọn fídíò fún Luk 10:40-42