Luk 10:1-20

Luk 10:1-20 YBCV

LẸHIN nkan wọnyi, Oluwa si yàn adọrin ọmọ-ẹhin miran pẹlu, o si rán wọn ni mejimeji lọ ṣaju rẹ̀, si gbogbo ilu ati ibi ti on tikararẹ̀ yio gbé de. O si wi fun wọn pe, Ikore pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan: nitorina ẹ bẹ̀ Oluwa ikore, ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikore rẹ̀. Ẹ mu ọ̀na nyin pọ̀n: sa wò o, emi rán nyin lọ bi ọdọ-agutan sãrin ikõkò. Ẹ máṣe mu asuwọn, ẹ máṣe mu apò, tabi bàta: ẹ má si ṣe kí ẹnikẹni li ọ̀na. Ni ilekile ti ẹnyin ba wọ̀, ki ẹ kọ́ wipe, Alafia fun ile yi. Bi ọmọ alafia ba si mbẹ nibẹ̀, alafia nyin yio bà le e: ṣugbọn bi kò ba si, yio tún pada sọdọ nyin. Ni ile kanna ni ki ẹnyin ki o si gbé, ki ẹ mã jẹ, ki ẹ si mã mu ohunkohun ti nwọn ba fifun nyin; nitori ọ̀ya alagbaṣe tọ́ si i. Ẹ maṣe ṣi lati ile de ile. Ati ni ilukilu ti ẹnyin ba wọ̀, ti nwọn ba si gbà nyin, ẹ jẹ ohunkohun ti a ba gbé kà iwaju nyin: Ẹ si mu awọn alaisan ti mbẹ ninu rẹ̀ larada, ki ẹ si wi fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin. Ṣugbọn ni ilukilu ti ẹnyin ba si wọ̀, ti nwọn kò ba si gbà nyin, nigbati ẹnyin ba si jade si igboro ilu na, ki ẹnyin ki o si wipe, Ekuru iyekuru ilu nyin ti o kù si wa lara, a gbọn ọ silẹ fun nyin: ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ si nyin. Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ni ijọ na, jù fun ilu na lọ. Egbé ni fun iwọ, Korasini! Egbé ni fun iwọ, Betsaida! nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin, ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai, nwọn iba si joko ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru. Ṣugbọn yio san fun Tire on Sidoni nigba idajọ jù fun ẹnyin lọ. Ati iwọ, Kapernaumu, a o ha gbe ọ ga de oke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ de ipo-oku. Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi. Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ. O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá. Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara. Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.