Li oṣù kẹfa a si rán angẹli Gabrieli lati ọdọ Ọlọrun lọ si ilu kan ni Galili, ti a npè ni Nasareti, Si wundia kan ti a fẹ fun ọkunrin kan, ti a npè ni Josefu, ti idile Dafidi; orukọ wundia na a si ma jẹ Maria. Angẹli na si tọ̀ ọ wá, o ni, Alãfia iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin. Ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò lelẹ nitori ọ̀rọ na, o si rò ninu ara rẹ̀ pe, irú kíki kili eyi. Angẹli na si wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun. Sá si kiyesi i, iwọ o lóyun ninu rẹ, iwọ o si bí ọmọkunrin kan, iwọ o si pè orukọ rẹ̀ ni JESU. On o pọ̀, Ọmọ Ọgá-ogo julọ li a o si ma pè e: Oluwa Ọlọrun yio si fi itẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fun u: Yio si jọba ni ile Jakọbu titi aiye; ijọba rẹ̀ ki yio si ni ipẹkun. Nigbana ni Maria wi fun angẹli na pe, Eyi yio ha ti ṣe ri bẹ̃, nigbati emi kò ti mọ̀ ọkunrin? Angẹli na si dahùn o si wi fun u pe, Ẹmí Mimọ́ yio tọ̀ ọ wá, ati agbara Ọgá-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ́ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li a o ma pè e.
Kà Luk 1
Feti si Luk 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 1:26-35
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò