Ṣugbọn angẹli na wi fun u pe, Má bẹ̀ru, Sakariah: nitoriti adura rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yio si bí ọmọkunrin kan fun ọ, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Johanu. Iwọ o si li ayọ̀ ati inu didùn: enia pipọ yio si yọ̀ si ibí rẹ̀. Nitori on o pọ̀ niwaju Oluwa, kì yio si mu ọti-waini, bẹ̃ni kì yio si mu ọti-lile; yio si kún fun Ẹmi Mimọ́ ani lati inu iya rẹ̀ wá. On o si pa pipọ da ninu awọn ọmọ Israeli si Oluwa Ọlọrun wọn. Ẹmí ati agbara Elijah ni on o si fi ṣaju rẹ̀ lọ, lati pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ti awọn alaigbọran si ọgbọ́n awọn olõtọ; ki o le pèse enia ti a mura silẹ dè Oluwa.
Kà Luk 1
Feti si Luk 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 1:13-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò