Lef 27
27
Àwọn Òfin tí Ó Jẹmọ́ Ohun tí a fi fún OLUWA
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ.
3Idiyelé rẹ fun ọkunrin yio si jẹ́ lati ẹni ogún ọdún lọ titi di ọgọta ọdún, idiyelé rẹ yio si jẹ́ ãdọta ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́.
4Bi on ba si ṣe obinrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ọgbọ̀n ṣekeli.
5Bi o ba si ṣepe lati ọmọ ọdún marun lọ, titi di ẹni ogún ọdún, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ogún ṣekeli fun ọkunrin, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.
6Bi o ba si ṣepe lati ọmọ oṣù kan lọ titi di ọmọ ọdún marun, njẹ ki idiyelé rẹ fun ọkunrin ki o jẹ́ ṣekeli fadakà marun, ati fun obinrin, idiyelé rẹ yio jẹ ṣekeli fadakà mẹta.
7Bi o ba si ṣe lati ẹni ọgọta ọdún lọ tabi jù bẹ̃ lọ; bi o ba jẹ́ ọkunrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ṣekeli mẹdogun, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.
8Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e.
9Bi o ba si ṣepe ẹran ni, ninu eyiti enia mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ OLUWA wá, gbogbo eyiti ẹnikẹni ba múwa ninu irú nkan wọnni fun OLUWA ki o jẹ́ mimọ́.
10On kò gbọdọ pa a dà, bẹ̃ni kò gbọdọ pàrọ rẹ̀, rere fun buburu, tabi buburu fun rere: bi o ba ṣepe yio pàrọ rẹ̀ rára, ẹran fun ẹran, njẹ on ati ipàrọ rẹ̀ yio si jẹ́ mimọ́.
11Bi o ba si ṣepe ẹran alaimọ́ kan ni, ninu eyiti nwọn kò mú rubọ si OLUWA, njẹ ki o mú ẹran na wá siwaju alufa:
12Ki alufa ki o si diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi iwọ alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.
13Ṣugbọn bi o ba fẹ́ rà a pada rára, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ kún idiyelé rẹ.
14Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.
15Ati bi ẹniti o yà a sọ̀tọ ba nfẹ́ rà ile rẹ̀ pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ̀ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.
16Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà.
17Bi o ba yà oko rẹ̀ sọ̀tọ lati ọdún jubeli wá, gẹgẹ bi idiyelé rẹ bẹ̃ni ki o ri.
18Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ.
19Ati bi ẹniti o yà oko na sọtọ̀ ba fẹ́ rà a pada, njẹ ki o fi idamarun owo idiyelé rẹ kún u, yio si jẹ́ tirẹ̀.
20Bi on kò ba si fẹ́ rà oko na pada, tabi bi o ba ti tà oko na fun ẹlomiran, ki a máṣe rà a pada mọ́.
21Ṣugbọn oko na, nigbati o ba yọ li ọdún jubeli, ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, bi oko ìya-sọtọ; iní rẹ̀ yio jẹ́ ti alufa.
22Ati bi ẹnikan ba yà oko kan sọ̀tọ fun OLUWA ti on ti rà, ti ki iṣe ninu oko ti o jogún;
23Njẹ ki alufa ki o ṣìro iye idiyelé rẹ̀ fun u, titi di ọdún jubeli: ki on ki o si fi idiyelé rẹ li ọjọ́ na, bi ohun mimọ́ fun OLUWA.
24Li ọdún jubeli ni ki oko na ki o pada sọdọ ẹniti o rà a, ani sọdọ rẹ̀ ti ẹniti ini ilẹ na iṣe.
25Ki gbogbo idiyelé rẹ ki o si jẹ́ gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́: ogún gera ni ṣekeli kan.
26Kìki akọ́bi ẹran, ti iṣe akọ́bi ti OLUWA, li ẹnikan kò gbọdọ yàsọtọ; ibaṣe akọmalu, tabi agutan: ti OLUWA ni.
27Bi o ba ṣe ti ẹran alaimọ́ ni, njẹ ki o gbà a silẹ gẹgẹ bi idiyelé rẹ, ki o si fi idamarun rẹ̀ kún u: tabi bi kò ba si rà a pada, njẹ ki a tà a, gẹgẹ bi idiyelé rẹ.
28Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA.
29Kò sí ẹni ìyasọtọ ti a ba yàsọtọ ninu enia, ti a le gbàsilẹ; pipa ni ki a pa a.
30Ati gbogbo idamẹwa ilẹ na ibaṣe ti irugbìn ilẹ na, tabi ti eso igi, ti OLUWA ni: mimọ́ ni fun OLUWA.
31Bi o ba ṣepe enia ba ràpada rára ninu ohun idamẹwa rẹ̀, ki o si fi idamarun kún u.
32Ati gbogbo idamẹwa ọwọ́ ẹran, tabi ti agbo-ẹran, ani ohunkohun ti o ba kọja labẹ ọpá, ki ẹkẹwa ki o jẹ́ mimọ́ fun OLUWA.
33Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada.
34Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Lef 27: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.