Ki o si gbà ọmọ ewurẹ meji akọ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan fun ẹbọ sisun, lọwọ ijọ awọn ọmọ Israeli. Ki Aaroni ki o si fi akọmalu ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikara rẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀. Ki o si mú ewurẹ meji nì, ki o si mú wọn wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. Ki Aaroni ki o si di ìbo ewurẹ meji na; ìbo kan fun OLUWA, ati ìbo keji fun Asaseli (ewurẹ idasilẹlọ). Ki Aaroni ki o si mú ewurẹ ti ìbo OLUWA mú wá, ki o si fi ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ. Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli.
Kà Lef 16
Feti si Lef 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lef 16:5-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò