OLUWA si sọ fun Mose lẹhin ikú awọn ọmọ Aaroni meji, nigbati nwọn rubọ niwaju OLUWA, ti nwọn si kú;
OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni arakunrin rẹ, ki o máṣe wá nigbagbogbo sinu ibi mimọ́, ninu aṣọ-ikele niwaju itẹ́-ãnu, ti o wà lori apoti nì; ki o má ba kú: nitoripe emi o farahàn ninu awọsanma lori itẹ́-ãnu.
Bayi ni ki Aaroni ki o ma wá sinu ibi mimọ́: pẹlu ẹgbọrọ akọmalu fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo fun ẹbọ sisun.
Ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ mimọ́ wọ̀, ki o si bọ̀ ṣòkoto ọ̀gbọ nì si ara rẹ̀, ki a si fi amure ọ̀gbọ kan dì i, fila ọ̀gbọ ni ki a fi ṣe e li ọṣọ́: aṣọ mimọ́ ni wọnyi; nitorina ni o ṣe wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si mú wọn wọ̀.
Ki o si gbà ọmọ ewurẹ meji akọ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan fun ẹbọ sisun, lọwọ ijọ awọn ọmọ Israeli.
Ki Aaroni ki o si fi akọmalu ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikara rẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀.
Ki o si mú ewurẹ meji nì, ki o si mú wọn wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
Ki Aaroni ki o si di ìbo ewurẹ meji na; ìbo kan fun OLUWA, ati ìbo keji fun Asaseli (ewurẹ idasilẹlọ).
Ki Aaroni ki o si mú ewurẹ ti ìbo OLUWA mú wá, ki o si fi ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli.
Ki Aaroni ki o si mú akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá, ti iṣe ti on tikararẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ki o si pa akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti iṣe fun ara rẹ̀:
Ki o si mú awo-turari ti o kún fun ẹyin iná lati ori pẹpẹ wá lati iwaju OLUWA, ki ọwọ́ rẹ̀ ki o si kún fun turari didùn ti a gún kunná, ki o si mú u wá sinu aṣọ-ikele:
Ki o si fi turari na sinu iná niwaju OLUWA, ki ẽfin turari ki o le bò itẹ́-ãnu ti mbẹ lori ẹri, ki on ki o má ba kú.
Ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si fi ika rẹ̀ wọn ọ sori itẹ́-ãnu ni ìha ìla-õrùn; ati niwaju itẹ́-ãnu ni ki o fi ìka rẹ̀ wọ́n ninu ẹ̀jẹ na nigba meje.
Nigbana ni ki o pa ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, eyiti iṣe ti awọn enia, ki o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu aṣọ-ikele, ki o si fi ẹ̀jẹ na ṣe bi o ti fi ẹ̀jẹ akọmalu ṣe, ki o si fi wọ́n ori itẹ̀-ãnu, ati niwaju itẹ́-ãnu:
Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́ nì, nitori aimọ́ awọn ọmọ Israeli, ati nitori irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn: bẹ̃ni ki o si ṣe si agọ́ ajọ, ti mbẹ lọdọ wọn ninu aimọ́ wọn.
Ki o má si sí ẹnikan ninu agọ́ ajọ nigbati o ba wọle lati ṣètutu ninu ibi mimọ́, titi yio fi jade, ti o si ti ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ati fun gbogbo ijọ enia Israeli.
Ki o si jade si ibi pẹpẹ ti mbẹ niwaju OLUWA, ki o si ṣètutu si i; ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ati ninu ẹ̀jẹ ewurẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ na yiká.
Ki o si fi ika rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ na wọ́n ara rẹ̀ nigba meje, ki o si wẹ̀ ẹ mọ́, ki o si yà a simimọ́ kuro ninu aimọ́ awọn ọmọ Israeli.
Nigbati o ba si pari ati ṣètutu si ibi mimọ́, ati si agọ́ ajọ, ati pẹpẹ, ki o mú ewurẹ alãye nì wá:
Ki Aaroni ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ mejeji lé ori ewurẹ alãye na, ki o si jẹwọ gbogbo aiṣedede awọn ọmọ Israeli sori rẹ̀, ati gbogbo irekọja wọn, ani gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn; ki o si fi wọn lé ori ewurẹ na, ki o si ti ọwọ́ ẹniti o yẹ rán a lọ si ijù:
Ki ewurẹ na ki o si rù gbogbo aiṣedede wọn lori rẹ̀ lọ si ilẹ ti a kò tẹ̀dó: ki o si jọwọ ewurẹ na lọwọ lọ sinu ijù.
Ki Aaroni ki o si wá sinu agọ́ ajọ, ki o si bọ́ aṣọ ọ̀gbọ wọnni silẹ, ti o múwọ̀ nigbati o wọ̀ ibi mimọ́ lọ, ki o si fi wọn sibẹ̀:
Ki o si fi omi wẹ̀ ara rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan, ki o si mú aṣọ rẹ̀ wọ̀, ki o si jade wá, ki o si ru ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ sisun awọn enia, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀ ati fun awọn enia.
Ọrá ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì ni ki o si sun lori pẹpẹ.
Ati ẹniti o jọwọ ewurẹ nì lọwọ lọ fun Asaseli, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.
Ati akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ewurẹ nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹ̀jẹ eyiti a múwa lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ni ki ẹnikan ki o mú jade lọ sẹhin ode ibudó; ki nwọn ki o si sun awọ wọn, ati ẹran wọn, ati igbẹ́ wọn ninu iná.
Ati ẹniti o sun wọn ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.