Lef 12

12
Ìwẹ̀nùmọ́ Àwọn Obinrin Lẹ́yìn Ìbímọ
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi obinrin kan ba lóyun, ti o si bi ọmọkunrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; gẹgẹ bi ọjọ́ ìyasọtọ fun ailera rẹ̀ ni ki o jẹ́ alaimọ́.
3Ni ijọ́ kẹjọ ni ki a si kọ ọmọkunrin na nilà.
4Ki obinrin na ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọjọ́ mẹtalelọgbọ̀n; ki o máṣe fọwọkàn ohun mimọ́ kan, bẹ̃ni ki o máṣe lọ sinu ibi mimọ́, titi ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ yio fi pé.
5Ṣugbọn bi o ba bi ọmọbinrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ li ọsẹ̀ meji, bi ti inu ìyasọtọ rẹ̀: ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọgọta ọjọ́ o le mẹfa.
6Nigbati ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ ba pé, fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, ki o mú ọdọ-agutan ọlọdún kan wá fun ẹbọ sisun, ati ẹiyẹle, tabi àdaba, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ ajọ:
7Ẹniti yio ru u niwaju OLUWA, ti yio si ṣètutu fun u; on o si di mimọ́ kuro ninu isun ẹ̀jẹ rẹ̀. Eyi li ofin fun ẹniti o bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.
8Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá; ọkan fun ẹbọ sisun, ati ekeji fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: alufa yio si ṣètutu fun u, on o si di mimọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Lef 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀