Awọn àgbagba ọmọbinrin Sioni joko ni ilẹ, nwọn dakẹ: nwọn ti ku ekuru sori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu sọ ori wọn kọ́ si ilẹ. Oju mi gbẹ tan fun omije, inu mi nho, a dà ẹ̀dọ mi sori ilẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi: nitoripe awọn ọmọ wẹ̃rẹ ati awọn ọmọ-ọmu nkulọ ni ita ilu na. Nwọn nsọ fun iya wọn pe, Nibo ni ọka ati ọti-waini gbe wà? nigbati nwọn daku gẹgẹ bi awọn ti a ṣalọgbẹ ni ita ilu na, nigbati ọkàn wọn dà jade li aiya iya wọn. Kili ohun ti emi o mu fi jẹri niwaju rẹ? kili ohun ti emi o fi ọ we, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu? kili emi o fi ba ọ dọgba, ki emi ba le tù ọ ninu, iwọ wundia ọmọbinrin Sioni? nitoripe ọgbẹ rẹ tobi gẹgẹ bi okun; tali o le wò ọ sàn?
Kà Ẹk. Jer 2
Feti si Ẹk. Jer 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ẹk. Jer 2:10-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò