Joṣ 7:1-2

Joṣ 7:1-2 YBCV

ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli. Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai.