O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn dide ni kùtukutu li afẹmọjumọ́, nwọn si yi ilu na ká gẹgẹ bi ti iṣaju lẹ̃meje: li ọjọ́ na nikanṣoṣo ni nwọn yi ilu na ká lẹ̃meje. O si ṣe ni ìgba keje, nigbati awọn alufa fọn ipè, ni Joṣua wi fun awọn enia pe, Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na. Ilu na yio si jẹ́ ìyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ̀: kìki Rahabu panṣaga ni yio là, on ati gbogbo awọn ti mbẹ ni ile pẹlu rẹ̀, nitoriti o pa awọn onṣẹ ti a rán mọ́. Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu ohun ìyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọ̀tọ tán ki ẹ si mú ninu ohun ìyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israeli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a. Ṣugbọn gbogbo fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati ti irin, mimọ́ ni fun OLUWA: nwọn o wá sinu iṣura OLUWA.
Kà Joṣ 6
Feti si Joṣ 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Joṣ 6:15-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò